Pelu bi eto idibo gbogbo-gbo odun 2015 se n sun mo werewere, ti awon egbe oselu gbogbo ti n sise labenu lati le jawe olubori ninu awon idibo lolokan-o-jokan, wahala gidi legbe oselu Action Alliance (AA) ipinle Oyo n ba ara won fa bayii,
Bi e ti n kowe si mi ni mo n ri i ka, oro ti e si n so n ye mi. Eyin ti e n mura pe a gbodo da egbe sile, ko si ohun to buru nibe, bi e ba n ri ara yin, e maa ko ara yin jo, ki e saa ti mo pe ki i se egbe oselu, nigba ti asiko ba to, a o pe ara wa jo soju kan.
Omokunrin atamase egbe agbaboolu Enyimba nni, Sibi Gwar, tun ti bere si i da goolu sawon bayii gege bii ise re. Opin ose to koja yii ni omokunrin eni odun meeedogbon naa pa Kano Pillars to gba ife-eye saa to koja lekun pelu boolu meta to gba wole laarin ogoji iseju.
Koosi egbe agbaboolu Flying Eagles, John Obuh ti gbe oruko oga awon agbaboolu ogbon jade fun idije agbaye ti yoo bere lojo kokanlelogun, osu to n bo. Ninu won la ti ri mejidinlogun lara awon to kopa nibi idije ile Afrika to sese pari, nigba ti awon mejila to ku je agbaboolu tuntun.